Ẹ̀yin ọ̀dọ́

Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Yorùbá, lọ́kùnrin àti lóbìnrin.

Ni orukọ awọn agbaagba ipinlẹ Yorùbá, awa akojọpọ asewadi Odua Research Group (ORG) fẹ fi akoko yi ki ẹyin ọdọmọkunrin ati ọdọmọbirin ilẹ Yorùbá. O jẹ nkan ibanujẹ pupọ lati ri wipe awọn alagba ilẹ Yorùbá ti fa ibajẹ pupọ fun orilẹ èdè  wa. Nwọn ti sọ orilẹ èdè  ti ibati jẹ ilu olokiki ni ọjọ oni di ẹdun arinlẹ fun ẹyin ọdọ. Nipasẹ iwa imọtara-ẹni-nikan, iwọra, ole jija, janduku, aiṣotitọ, ọdalẹ, wọbia, aini’wa ati ailojuti ọpọlọpọ wọn, nwọn ti ta awọn ẹmi wọn ati ọjọ-ọla ẹyin ọdọ Yorùbá fun awọn amunisin bi ẹrú. O jẹ ibanujẹ wipe awọn alagba ati adari, paapaa julọ, awọn ti nwọn jẹ ọmọwe pẹlu gbogbo oye ti nwọn gba ni ile ẹkọ giga, ko wu iwa ọmoluabi nipasi tita ọjọ-iwaju ọdọ Yorùbá fun awọn iran darandaran ti ko k’awe to wọn.

Ṣugbọn ni ọjọ oni, o yẹ ki ẹ fi ọwọ sọya, ki o si jẹ nkan idunu fun ẹyin ọdọ wipe oju nyin ti la. Oye yin si ti pe. O jẹ nkan idunu wipe ẹyin ọdọ ti dide duro lati sọ fun awọn alagba jẹgudujẹra wipe, ibajẹ ti wọn da si ilẹ Yorùbá ti to gẹ

Ọkan ninu awọn aṣeyọri ti o tobi julọ ni wipe gbogbo eniyan ti mọ nisinsinyi, isoro ati igbekun ti ilẹ Yorùbá wa ni ọjọ oni. Nisinsinyi, awọn ọdọ ti mọ orisun awọn iṣoro ti odoju kọ nwọn.
Gbogbo eniyan ni o nsọrọ soke nipa wahala ti o de bawa. Awọn opurọ oludari ilẹ Yorùbá ko ni iboji ti nwọn le sa pamọ si mọ.

O ti han gbangba wipe aini idagbasoke ni ilẹ Yorùbá jẹ abajade taara ti aini aṣaaju ododo ọmọ Yorùbá. O ti han gbangba wipe idi ti eto-ẹkọ ati awọn amayedẹrun ti o wa tẹlẹ ni aiye atijọ paapaa ni akoko ti Naijiria gba ominira ti di iparun patapata. Awọn ọdọ mọ bayi idi ti ofi jẹ wipe lẹhin ipari ẹkọ wọn ni aṣeyọri, ati ri isẹ se di wahala fun wọn. Idamu airijẹ at airimu ti sọ ọpọlọpọ ninu wọn di ọdaran ti on da ọwọ le iṣẹ arufin bi yahoo-yahoo gẹgẹ bi ọna miiran lati ri onjẹ oojọ wọn.

Nwọn ti ṣe akiyesi bayi idi ti eto ilera naa jẹ ti igba atijọ ti ko ni idagbasoke. Nwọn ti mọ idi  ti awọn amayedẹrun bii ipese ina ẹlẹtriki, awọn opopona ti o dara, omi ẹrọ, gbogbo awọn nkan ti awọn orilẹ-èdè  miran npese fun awọn eniyan wọn ko si ni ilẹ Yorùbá.

Awọn ọdọ Yorùbá ti mọ nisinsinyi wipe awọn aṣaaju Yorùbá funra wọn ni ọta ti ogajulọ fun orilẹ-èdè  wọn. Awọn aṣaaju Yorùbá ni ogbaaye fun awọn darandaran onisẹ-ibi Fulani ti onwọ orilẹ-èdè  Yorùbá. Awọn agba Yorùbá ni onpa owe wipe, bi ogiri ko ba lanu, alangba ko le ri aye wọbẹ.

Awọn agba Yorùbá ni idi fun aini aabo ati onigbọwọ si awọn ẹmi ati awọn ohun-ini ni ilẹ Yorùbá. Awọn ni idi fun awọn ipaniyan, iparun apanirun si awọn ohun-ini ati igbesi-aye ti awọn eniyan ni orilẹ-èdè  Yorùbá. Awọn ni idi fun jiji ati ifipa banilopọ ati awọn iwa ika miiran ti a nri ni ilẹ Yorùbá. Gbogbo awọn iṣoro ati ilahilo wọnyi jẹ ki o ṣeeṣe, nitori iwa ole, iwa ika at ti aimọtara-ẹni-nikan ti awọn aṣaaju Yorùbá, paapaa julọ awọn oloṣelu, awọn gomina Ipinlẹ ati awọn adari ibilẹ.

Ohun ija kan soso ti oku si ọwọ awọn jẹgudujẹra asaaju orilẹ ede Yoruba bayi ni lati dẹruba gbogbo eniyan. Nwọn ti bẹrẹ si ni polongo wipe ibere fun ominira fun orilẹ-ede Yoruba yoo ja si ogun. Lati le mu awọn eniyan ni irẹwẹsi, awọn oniwa ibajẹ pẹlu awọn oloṣelu arijẹnimodaru ti o njẹ anfani lati idarudapọ ti bẹrẹ si ni kọ orin ogun. Nwọn nkọrin nipa Rwanda ati Sudan. Nwọn nkọrin nipa Somalia ati Ethiopia. Nwọn nkọrin nipa Yugoslavia ati ogun abẹlẹ Naijiria.

Ojẹ ibanujẹ pupọ wipe ọpọlọpọ ninu awọn ọba, awọn ijoye, awọn oloṣelu, awọn adari ibilẹ, awọn gomina ipinlẹ, awọn agbagba, ati awọn aṣaaju ijọ ẹlẹsin ni awọn ọta tootọ fun awọn ọmọ Yorùbá.

"" ... Idi fun aini aabo ati onigbọwọ si awọn ẹmi ati ohun-ini ni ilẹ Yoruba, awọn ipaniyan, iparun apanirun si awọn ohun-ini ati igbesi-aye ti awọn eniyan ti n ṣiṣẹ takuntakun ti ile Yoruba, jiji ati ifipabanilopo ti awọn alailẹṣẹ ati awọn iwa ika miiran ti o jẹri ni ilẹ Yoruba nikan ṣẹlẹ nitori awọn aṣaaju Yoruba jẹ iṣiro..""

Ogun naa yoo bori. Iwọ yoo jẹ ẹlẹri si iṣẹgun ati ominira kikun ti Oodua Republic. O jẹ igbiyanju ominira. Ko si ẹniti o le da a duro.

Gbogbo awọn ifẹ ti o dara julọ fun Oodua Republic olominira.

Ẹ̀yin ọmọ órílẹ-èdè Yorùbá,
O ti han gbangba bayi wipe awọn ọta eniyan wa pẹlu awọn ọdalẹ alai lojuti oludari ati aṣaaju órílẹ-èdè wa ko ronu jinlẹ rara. Aisododo wọn ti mu ki nwọn padanu ẹmi ati ọkan lati ṣe ojuṣe wọn fun awọn ọmọ ile Yorùbá. Eyi ni idi ti awọn kan ninu wọn fi lodi si isọrọ ipinnu nipa gbigba ominira fun órílẹ-èdè wa. Otitọ kankan ko si ni ẹnu wọn. Nwọn ti di ẹru fun awọn Fulani amunisin. Ṣugbọn igba tiwọn ti pari. Akoko tiwọn ti kọja. Akoko fun igbese pataki ti de lati gba ominira lọwọ wọn. Akoko ti de nisinsinyi nigbati oju yoo ti awọn olori wọnyi ati awọn amunisin ti ondari wọn.

Odua Research Group